Ẹlẹ́kẹrìnlá irú rẹ àjọ ipade ẹyẹ Adari ilé Adúláwọ̀ tí wọ́n gbékalẹ̀ lábẹ́ àjọ UN International Peace Governance Council (UNIPGC), ẹ̀ka ilẹ̀ Adúláwọ̀ yóò fi àmì ẹyẹ ọlọlá- Grand Commander of Peace fún Ọba Adeyeye Babatunde Enitan Ogunwusi, Ojaja II, Ooni ti Ilé-Ifẹ̀ , ipinlẹ Ọsun, iwọ oorun gúsù Nàìjíríà.
Ayẹyẹ náà yóò wáyé ní Nigerian Institute of International Affairs (NIIA), ìlú Èkó. Láti mọ riri ọba alaye tó tún jẹ Bàbá fún akitiyan wọn fún ẹwà àṣà ilẹ̀ Áfríkà káàkiri gbogbo àgbáyé.
Àwọn ènìyàn pàtàkì ilẹ̀ Adúláwọ̀ ti wọn yóò tún da lọ́lá ní, Dókítà
Hussein Ali Mwinyi ti yóò gba Ẹ̀bùn pàtàkì Olùtayọ ìlà oòrùn Adúláwọ̀ olùrànlọwọ ti ààrẹ fún àwọn obìnrin ati ìlera àwọn èwe
ní ìlà iwọ oòrùn Áfríkà. Wọn a sì tún fi oyè Grand Commander of Peace (GCOP) da lọla ní abẹ́ àjọ
United Nations Sustainable Development Goal (UN SDG 16) – Peace, Justice, and Strong Institutions.
Bí ààrẹ àjọ àpapọ̀ UNIPGC, Dókítà Jonathan Ojadah, ṣe sọ
akitiyan Ali Mwinyi ní àwọn agbègbè yìí ló fa àwọn ami ẹyẹ ti wọn fi dáa lọla, ó sọ pé gbogbo àwọn akitiyan wọ̀nyí a máa mú kí èmí àwọn ìyá àti ọmọ àsẹ̀sẹ̀bí gùn, o wà rọ àwọn èèkàn ni àwùjọ láti gbárùkù tì wọ́n ki àwọn ètò dára dára náà
leè máa tẹ síwájú.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san