Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Tẹ́lẹ̀rí Olusẹgun Ọbasanjọ Se Ayẹyẹ Ọjọ́ Ìbí Ọdún Méjìdínláàdọ́ọ̀rún, Gọngọ Sọ
Ààrẹ Orílẹ̀-èdè tẹ́lẹ̀rí, Olusẹgun Ọbasanjọ ti ké sí àwọn ọmọ Naijiria, papàá jùlọ àwọn ọ̀dọ́ láti ko ipa tí ó làmì-laaka èyí tí yóò mú Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà dé ilẹ̀ ìlérí
Ọbasanjọ pàrọwà sí àwọn ọmọ Nàìjíríà láti fi ọwọ́ sowópọ̀ fún ìsọ̀kan, ìdàgbàsókè àti ìtẹ̀síwájú Orílẹ̀-èdè wa
Ó sọ ọ̀rọ̀ náà ní ìlú Abeokuta, Ìpínlẹ̀ Ògùn nígbà tí ó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn fún àyẹ́sí, àpọ́nlé tí wọ́n fún-un níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún kejìdínláàdọ́ọ̀rún èyí tí ó wáyé ní ilé Ìkàwé Olusẹgun Ọbasanjọ ní ìlú Abẹokuta
Ó tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ lásìkò ayẹyẹ náà èyí tí àwọn ọ̀tọ̀ǹkùlú ìlú, alẹ́nulọ́rọ̀, Ọba Alayé, àwọn Gomina ati awọn Aarẹ tẹlẹri peju si, ó sàfirinlẹ̀ àrídájú pé ọjọ́ iwájú Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò dára, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń kojú ọlọ́kan-ò-jọ̀kan ìpèníjà lásìkò tí a wà yìí