Take a fresh look at your lifestyle.

Ìwà ìbàjẹ́ Nípa Owó Oṣù: Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano Dá Olórí Àwọn Òṣìṣẹ́ Dúró Náà.

125

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano, Abba Kabir Yusuf tí da adelé olórí ẹ̀gbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ duro náà, Salisu Mustapha, látàrí bi wọn ṣe n ṣe owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ ni ọna ti ko dá.

Àtẹ̀jade kan tó wà láti agbẹnusọ fún Gómìnà, Sanusi Bature sọ wí pé, àṣẹ ti jade wí pé kí Mustapha kúrò ni ipò Akòwé àgbà, labẹ ilé iṣé ìjọba fún àwọn òṣìṣẹ́, ki ètò íwáàdí náà ba le wáyé ni kíákíá.

Láti rí wí pé ilé iṣé ìjọba tèsíwájú Gómìnà ti Yan Malam Umar Muhammad Kali gẹ́gẹ́ bí adarí àgbà tuntun fún ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́.

Bákannáà wọn ti yan àwọn ìgbìmọ̀ láti ṣe ìwádìí lori ohun tí o sẹlẹ.

Àwọn ìgbìmọ̀ náà ṣe ìlérí wí pé ní orúkọ Gómìnà Yusuf àwọn yóò fi oju asebi hàn léyìn íwáàdí náà.

Wọn ní Gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ni yóò rí àtúnṣe nlá àti ẹ̀tọ́ wọn lásìkò.

Gómìnà Yusuf sọ wí pé labẹ ìjọba òun kì yóò sí àyè fún ìwà ìbàjẹ́ láàrin àwọn òṣìṣẹ́ ni ìpínlẹ̀ náà.

Comments are closed.

button