Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu tí ṣé ìlérí láti túbọ̀ sápá òun sí lórí àṣeyọrí oúnjẹ, ìdókòwò àti ìdàgbàsókè jákèjádò orílẹ̀-èdè náà.
O ṣé ìlérí náà ní Abuja, Olú-ìlú Orílẹ-èdè l’àkókò tí gbogbo àwọn ọmọ ‘All Progressive Congress APC’, fí ìgbàgbọ́ wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí adari réré.

Ààrẹ Tinubu ṣàpèjúwe ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà gẹ́gẹ́bí ìpèníjà láti ṣiṣẹ́ takun-takun síi àti látí mú ìdàgbàsókè bá ètò-ọrọ àjé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jú tilẹ̀ lọ́.

Ìpàdé Ìgbìmọ̀ Àwọn Aláṣẹ tí ‘APC’ náà ló wáyé ní Ọjọ́rú. Níbí ìpàdé náà ní àwọn Olùdarí ẹgbẹ́ náà tún gbóríyìn fún ìṣàkóso Ààrẹ Tinubu fún yiyi ọrọ-àjé Orílẹ̀-èdè náà pàdà sí dáadáa.
Comments are closed.