Kò sí Ìfọ̀kànbalẹ̀ Ní Zamzam, Orílẹ̀-èdè Sudan Látàrí Rúkè-rúdò Tí Ó Ń Wáyé- Àjọ UN
Agbẹnusọ akọ̀wé àpapọ̀ àjọ àgbáyé ti sàlàyé pé rúkè-rúdò tí ó ń wáyé ní Orílẹ̀-èdè Sudan ti fa ìdààmú dààbo, àìfàyàbalẹ̀ ọkàn, tí ó sì mú kí ìgbé ayé le koko ní àgbègbè náà
Ọ̀gbẹ́ni Stephane Dujarric sọ pe Zamzan jẹ́ ọ̀kan nínú àgbègbè tí ẹbi ti ń pa àwọn ènìyàn látàrí wàhálà tí ó ń wáyé ní àgbègbè náà èyí tí ó ti mú kí àwọn ènìyàn tí ó dín díẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà sá àsálà fún ẹ̀mí wọn láti wá ìdáàbò bò ní àgbègbè Al Fasher
Ìròyìn fi yéwa pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó tún ti ń gbèrò láti fi àgbègbè náà sílẹ̀ sùgbọ́n ìgbésẹ̀ ti ń wáyé láti yanjú aáwọ̀ náà èyí tí yóò mú kí àlàáfíà jọba