Ìròyìn Ayọ̀: Àrùn Ebola Di Ohun Àfìsẹ́yìn Tí Egúngún Ń Fi Asọ Ní Orílẹ̀-èdè Uganda- Minisita Ètò Ìlera
Ènìyàn mẹ́jọ tí àyẹ̀wò fi hàn pé àrùn Ebola ń yọ lẹ́nu nígbà tí àrùn náà súyọ ní ọ̀ṣẹ̀ tí ó kọjá ní ó ti wà ní ipò àlàáfíà, tí wọn si ti kúrò ní ilé ìwòsàn
Àjọ WHO gbósùbà fún ìjọba Orílẹ̀-èdè Uganda láti ara ìgbésẹ̀ kíákíá tí ó wáyé lójúnà àti dènà ìtànkálẹ̀ àìsàn náà
Ìjọba àti àwọn elétò ìlera ti wà ní ojú ni alákàn fi ń sọ́rí láti rí i dájú pé ogun tí ó ti ṣẹ́, kò tún gbórí mọ́