Take a fresh look at your lifestyle.

Erin Wó, Àjànàkú Sùn Bí Òkè, Edwin Clark Dágbére Fáyé, Adarí Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Sèdárò Lẹ́yìn Akọni

109

Adarí Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin, Ọ̀gbẹ́ni Abbas Tajudeen àti igbákejì rẹ̀ Benjamin Kalu ti sèdárò lẹ́yìn olóògbé, olóyè Edwin Kiagbodo Clark, wọ́n sàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí asíwájú rere tí ó fi gbogbo ara jì fún ìdàgbàsókè àgbègbè Niger Delta

 

Abbas sàlàyé pé lẹ́yìn ìgbà tí olóògbé Edwin Clark fẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba àti nínú òsèlú, kò kùnà nínú síṣe àtìlẹyìn rẹ̀ fún àgbègbè Niger Delta ti ìdàgbàsókè àgbègbè náà sì jẹ ẹ́ lógún

 

Ó fi ẹ̀dùn ọkàn hàn bí ikú olóògbé Edwin Clark se wáyé ní kòpẹ́ tí ojúgbà rẹ̀ tí ó jẹ́ adarí ẹgbẹ́ ìdàgbàsókè ọmọ Yorùbá, olóyè Ayọ Adebanjọ náà dágbére fáyé, èyí tí ó sàfihàn bí àwọn àgbààgbà se ń tán lórílẹ̀

 

Adarí Ilé Asòfin wa kẹ́dùn pẹ̀lú ìjọba ìpínlẹ̀ Delta, àwọn ènìyàn àgbègbè Niger Delta àti Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lápapọ̀, ó wá gbàdúrà kí Ọlọ́run tẹ́ Edwin Clark si afẹ́fẹ́ rere

Comments are closed.

button