Take a fresh look at your lifestyle.

Mímọ́ Tóní-tóní Ìpínlẹ̀ Èkó Jẹ Wá Lógún- Àjọ Tí Ó Ń Mójútó Ìgbálé-Gbáta Sọ̀rọ̀ Sókè

100

Àjọ LAWMA Ìpínlẹ̀ Èkó ti ń là kàkà láti rí i dájú pé Ìpínlẹ̀ Eko wà ní ìmọ́tótó ní gbogbo ìgbà, àtipé ẹni-kẹ́ni kò gbọdọ̀ da ìdọ̀tí sí ààyè tí kò yẹ

 

Alákòsóo Àjọ náà, Ọ̀mọ̀wé Muyiwa Gbadegẹsin sàfihàn ìgbáradì àjọ náà fún ìmọ́tótó Ìpínlẹ̀ Eko ní gbogbo ìgbà, àtipé ki àwọn ará ìlú tẹ̀lé àlàkalẹ̀ òfin nípa ìmọ́tótó ní gbogbo ìgbà

 

Ó sèkìlọ̀ pé, àìmòfin kì í se àwíjàre, àtipé ẹnikẹ́ni tí ó bá tàpá sí òfin ìmọ́tótó yóò fi imú kó ata òfin. Ó tẹ̀síwájú pé àjọ náà ti ń se àtúnṣe àyè ìdàdọ̀tí sí lọ́nà tí kò bá òfin mu èyí tí ó wà ní òpópónà márosẹ̀ Lekki si Epe àti àwọn ààyè míràn jákè-jádò Ìpínlẹ̀ Eko

 

Comments are closed.

button