Ilé ìgbìmọ̀ Aṣojú Sòfin ti kéde ikú Ìyáàfin Adewunmi Oriyomi Onanuga tó jẹ́ igbákejì Àgbà ilé ìgbìmọ̀ tó ń sójú fún Ikenne/Sagamu/Ariwa Remo Kòńsítúnsì Àpapọ̀ ìpínlẹ̀ Ògùn – Deputy Chief Whip of the House, representing the Ikenne/Sagamu/Remo North Federal Constituency of Ogun State.
Ó kú ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún, oṣù kínní, ọdún 2025 lẹ́yìn àìsàn ránpẹ́.
Wọ́n bí Ìyáàfin Onanuga ní ọjọ́ Kejì, oṣù Kejìlá ọdún 1965, ó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọba tó tẹramọ́sẹ́, adarí tó ní òye fún ọjọ iwájú tó tún jẹ́ alágbàwí fún Kònsítúẹ́sì rẹ̀ to sí tun ni ifẹ sí Kònsítúẹ́sì.
Wọ́n kọ́kọ́ dìbò yán sí ilé ìgbìmọ̀ ní ọdún 2019 ni abẹ́ Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC).
Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin sọ pé àwọn ẹbí yóò kéde ọjọ́ ìsìnkú rẹ̀ tí àsìkò bá tó.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san.