Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde ti Komisana fún ìròyìn àti ìlanilọ́yẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọmọọba Dọtun Oyelade fi síta pé lẹ́yìn àyẹ̀wò finnifinni, ìgbìmọ̀ Ọ̀yọ́mèsì ti fa Ọmọọba Abímbólá Akeem Owoade sílẹ̀ fún ipò Aláàfin nígbà ti Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fi ọwọ́ sí Ìyànsípò náà.
Bákan náà ni Oyelade jẹ́ kó di mímọ̀ pé, Komisana fún Ìjọba Ìbílẹ̀ àti Òye jíjẹ, Ademola Ojo ti ṣàlàyé nínú àtẹ̀jáde tó fi síta pé ìkéde yìí tí mu kí ẹjọ àti awuyewuye lórí ipò Aláàfin eléyìí to ti ṣofo láti ìgbà tí Ọba Lamidi Adeyemi III ti wàjà, ni ọjọ́ Kejìlélógún oṣù Kẹrin ọdún 2022 (22/04/2022) wà sí òpin.
Ademola Ojo wa kẹ sì gbogbo ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lápapọ̀ láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba lójúnà àti yọ ayọ lórí eyi ki wọn sì ṣe àtìlẹyìn fún Aláàfin tuntun náà.
Oyelade wa gbàdúrà kí igba ati asiko Ọba náà mú àlàáfíà, ọrọ̀ àti ìṣọ̀kan dé bá ìlú Ọ̀yọ́.
Abiola Olowe
Ìbàdàn