Ilé iṣé Aláàdáni tí nṣe Ìrànlọ́wọ́ fún àwọn Obìnrin tí kéde wí pé àwọn yóò bèrè sí ni Dẹkun ìwà Ọkùnrin Jù Obìnrin èyí tí ko fi àye gbà àwọn obìnrin lati rówó mú ni ìpínlẹ̀ Enugu.
Adarí àgbà fún ilẹ isé náà, iyaafin Amala Nweke ló sọ èyí di mímọ̀ nígbà tí wọn n fi sọrọ wá lẹnu wò ni ìpínlẹ̀ Enugu.
Ó ní ohùn ti àwọn n gbọ nípa ìwà yìí ko dun mọ àwọn nínú rárá nitori náà àwọn tí bèrè iṣé lori rẹ láti dẹkùn rẹ.
Pàápàá jùlọ ló àwọn òfin ìgbà àtijọ́ ti o n ṣe àkóbá fún àwọn nínú ago-ara wọn
Ó ni kò sí àyè fún irú bẹẹ láàrin àwọn rárá.
Ó tún tèsíwájú wí pé àwọn ti n ṣe ìdánilékòó ni àwọn agbègbè kánkan láti rí wí pé ìwà ìbàjẹ́ náà di ohun ìgbà gbé.
Ó ni ìwà yìí n mu ọpọlọpọ wàhálà ba àwọn Obìnrin, pàápàá jùlọ àwọn omidan.