Gómìnà ìpínlẹ Katsina, Mallam Dikko Umaru Radda ti buwólu àtúntò àwọn alábàásisẹ́pọ̀ ìjọba pẹ̀lú èròńgbà láti mú ìdàgbàsókè bá ìpínlẹ̀ náà
Nínú ìfọ̀rọ̀léde láti ọwọ́ olùfọ̀rọ̀léde sí gomina, Ibrahim Kaulaha Muhammed salaye pe Alhaji Malik Anas ti o jẹ kọmísọ́nà tuntun ni yoo maa darí ètò ọrọ̀ ajé, nígbà tí Alhaji Bello Husaini ti o jẹ adari eto ọrọ aje tẹlẹri yoo dari eto ìsúná owó.
Bashir Tanimu Gambo kúrò ní ẹka isuna owo lọ sí ẹka ìsàkóso ijọba ìbílẹ̀ ati ọ̀rọ̀ oyè. Gómìnà pàrọwà si awọn kọmísọ́nà náà láti tẹ̀síwájú nínú ojúse wọn lójúnà àti mú ìdàgbàsókè bá ìpínlẹ̀ Katsina