Gómìnà Babagana Umara Zulum darí ìpàdé àpérò àkọ́kọ́ fún ọdún 2025 níbi tí ó ti sàgbéyẹ̀wò àwọn àseyorí tí ó wáyé ní ọdún 2024, Ó sì buwọ́lu àwọn iṣẹ́ àkànse tí wọn yóò dáwọ́lé
Níbi àpérò náà, gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn ni ó péjú-pésẹ̀ níbi tí a ti rí òǹkà ènìyàn mọ́kànlélógójì, tí wọn jíròrò, wọ́n sì ní ìfẹnukò
Ìpàdé naa dá lórí ìsàgbéyẹ̀wò àwọn àseyọrí tí ó ti wáyé, fífi ìpìlẹ̀ ìdàgbàsókè aláìlẹ́gbẹ́ lọ́lẹ̀ fún ti ọdún 2025. Lára ìfẹnukò ìpàdé àpérò náà nì wọ̀nyí: mímú ìyípadà bá orukọ Yunifasiti Ipinlẹ Borno ti yóò máa jẹ́ Kashim Ibrahim Yunifasiti, yíyan àwọn kọmísọ́nà ẹka ìjọba, fífún òpópónà lórúkọ, sísọ òpópónà Pápákọ̀ òfurufú Muhammadu Buhari di oníbejì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ