Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà Gbósùbà Fún Sẹ́nétọ̀ Nwebonyi Látàrí Síṣe Ìrànlọ́wọ́ Fún Àwọn Ènìyàn Ìpínlẹ̀ Ebonyi

241

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ebonyi, Ọ̀gbẹ́ni Francis Nwifuru ti sàpèjúwe Sẹ́nétọ̀ Onyekachi Nwebonyi gẹ́gẹ́ bi adarí rere tí ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ atipe o jẹ ohun àmúyangàn fún ìpínlẹ̀ Ebonyi

Gómìnà sàpèjúwe ìgbésẹ̀ Nwebonyi gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó mú ìdàgbàsókè bá àwọn ọ̀dọ́ àti ìpèsè iṣẹ

Gómìnà sọ ọ̀rọ̀ náà ní ilé ìjọsìn Saint Micheal, ni Mbeke Ishieke, ìjọba ìbílẹ̀ Ebonyi níbi ìfilọ́lẹ̀ ètò ìrọgun-síni-lápá náà, níbit́i sẹ́nétò Nwebonyi ti fi ọkọ̀ akérò ogún, kẹ̀kẹ́ nàpẹ́ẹ̀pù ogún, masín-ìn-rìn Alùpùpù ọgọ́rùn-ún àti ọ̀kẹ́ àìmọye owó se ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ènìyàn ‘rẹ̀

 

Comments are closed.

button