Àwọn Òbìlẹ̀jẹ́ Àádóta Ni Ó Fi Imú kó Ata Òfin Nípa Bíba Àwọn Ohun Amáyédẹrùn Jẹ́ Ní Ìlú Abuja
Àjọ Ọlọ́pàá tí Ìlú Abuja ti nawọ́ gán àwọn òbìlẹ̀jẹ́ àádọ́ta tí wọ́n ń ba àwọn ohun amáyédẹrùn jẹ́ ní ìlú Abuja
Kọmísọ́nà àjọ Ọlọ́pàá fún olú ìlú Orílẹ̀-èdè Naijiria , Ọlatunji Disu ni ó síṣọ lójú ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ó ń sàfihàn àwọn ọ̀daràn náà ní ìlú Abuja
Disu tẹ̀síwájú pé, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mẹ́ta, iná tí ó ń lo agbára òòrùn, àwọn irin, àti àwọn ohun èlò míràn ni wọn ba lọ́wọ́ awọn òbìlẹ̀jẹ́ náà
Ó fi àrídájú hàn pé gbogbo àwọn oníṣẹ́ láabi náà ní yóò fimú kó ata òfin