Ìgbé Ayé Yóò Di Gbẹdẹmukẹ Fún Ọmọ Nàìjíríà Ní Ọdún 2025- Ààrẹ Tinubu Fi Àrídájú Léde
Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu ti fi àrídájú léde, Ó sì fi ìrètí hàn pé ọjọ́ iwájú Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò dára àtipé ọdún ayọ̀ ni ọdún 2025 yóò jẹ́, èyí tí yóò kún fún wàrà àti oyin pẹ̀lú ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé àti oríire aláìlẹ́gbẹ́
Ó sọ ọ̀rọ̀ náà ní ọjọ́ Ajé nígbà tí ó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ìlú Èkó
Ààrẹ sàfihàn àwọn ìpèníjà tí ó ń kojú Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó sì pàrowà sí gbogbo ọmọ Nàìjíríà fún sùúrù àti àtẹ̀mọ́ra, ó wá fi àrídájú hàn pé dídùn ni ọsàn yóò so àtipé ayọ̀ ń bọ̀ lẹ́yìn ìnira ráńpẹ́ tí ó ti ń wáyé