Àjọ Ọmọ Ogun Ń Siṣẹ́ Takuntakun Láti Dáàbò Bo Ẹ̀mí Àti Dúkìá Ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà- Ààrẹ Tinubu Fi Ọwọ́ Sọ̀yà
Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Bọla Ahmed Tinubu ti gbósùbà fún àjọ Ọmọ Ogun Orílẹ̀-èdè Naijiria fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n n se, èyí tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú èròńgbà ìsèjọba Ààrẹ Tinubu láti rí i dájú pé ààbò wà fún ẹ̀mí àti dúkìá ará ìlú
Ààrẹ sọ ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ Ajé, ó sàfihàn ìlàkààkà ìsèjoba rẹ̀ láti rí i dájú pé ààbò tí ó péye wà, àtipé wàhálà àìrajaja ààbò ti ń kásẹ̀ nílẹ̀
Ààrẹ sàfihàn ìgbáradì ìjoba rẹ̀ láti pèsè àwọn ohun èlò ìjakun ìgbàlódé èyí tí ó ti mú kí àseyorí ńlá wáyé tí àwọn ọmọ ogun sì ń se àwọn alákatakítí báṣubàṣu ní ojoojúmọ́
Ó wá pàrọwà sí àjọ ọmọ ogun láti tẹ̀síwájú nínú akitiyan wọn èyí tí ó ti mú kih àlàáfíà jọba ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àyè ní Orílẹ̀-èdè Naijiria.