Ìjákulẹ̀ Dé Bámi Lórí Ètò Ẹ̀kọ́ Látàrí Ìsàfẹ́kù Owó Péréte- Ice Prince Sàlàyé Ọ̀rọ̀
Gbajúgbajà akọrin Panshak Zamani, tí gbogbo ayé mọ̀ sí Ice Prince ti sàlàyé ìpèníjà àti àwọn ìsòro tí ó kojú ninu ìgbé ayé rẹ̀ látàrí ìpàdánù àwọn òbí rẹ ati bí àwọn ìpèníjà náà se jẹ́ atọ́nà èyí tí ó mú u dé ilẹ̀ ìlérí
Nínú ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nu-wò kan tí ó wáyé, ó sàlàyé bí ó se pàdánù bàbá ti o bí i ní ẹni ọdún mọ́kànlá, tí ìyá sì kú nígbà tí ó wà ní ẹni ọdún mọ́kànlélógún
Àwọn ìsẹ̀lẹ̀ àti ìpèníjà náà ni kò jẹ́ kí o le e tẹ̀síwájú nínú ètò ẹ̀kọ́, sùgbọ́n pẹ̀lú iranlọwọ Ọlọrun Òun làmì-laaka nínú ayeh, o wa n lo ìrírí naa lati gba awọn ti o ba wa ninu irufẹ ipò bẹ́ẹ̀ ni akoko yii niyanju wipe bí a ò bá kú ìse kò tán, àtipé bí ẹ̀mí bá wà ìrètí sì wà.