Adarí Ilé Ìgbìmọ̀ Asoju Sòfin Nàìjíríà, Ọ̀gbẹ́ni Tajudeeen Abbas ti fi ọ̀rọ̀ léde wípé Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nílò tírílíọ̀nù mẹ́ta dọ́là láti pèsè àwọn ohun amáyédẹrùn ní gbèdéke ọgbọ̀n ọdún síwájú
Ó tẹ̀síwájú pé pípèsè òpópónà tí ó yè kooro, iná mọ̀nàmọ́ná tí ó múna dóko, ìpèsè ibùgbé àti ètò ìlera aláìlábàwọ́n àti àwọn ẹka pàtàkì míràn ni ó n fẹ́ àmójútó ní kíákíá
Ọ̀gbẹ́ni Abbas sísọ lójú ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ó ń se ìfilọ́lẹ̀ ìsàtúnṣe àti ìpèsè òpópónà tí ó lọ sí ibùgbé àwọn adájọ́ ní ìlú Abuja
Ó wá lo ànfààní náà láti gbósùbà fún ìsèjọba Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu fún mímú ìpèsè àwọn ohun amáyédẹrùn ní òkúkúdùn.