Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ Tẹ̀síwájú Láti Jẹ́ Olóòtọ́ọ́ Àti Nínú Iṣẹ́ Àsekára- Olurẹmi Tinubu Pàrọwà Sí Àwọn Ọ̀dọ́

160

Aya Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjírìà, Olurẹmi Tinubu ti pàrọwà sí àwọn ọ̀dọ́ láti tẹ̀síwájú nínú ojúse wọn fún síṣe iṣẹ́ àsekára àti jíjẹ́ olóòtọ́ọ́ láti jẹ́ ènìyàn rere tí yóò wúlò fún àwùjọ

 

Ó pe ìpè náà ní ọjọ́ Ìsẹ́gun ní ìlú Abuja níbi àpérò kan tí ó wáyé láti gbógunti ìwà jìbìtì orí ẹ̀rọ̀ ayélujára èyí tí àjọ tí ó ń gbógunti ìwà ìbàjẹ́ àti síṣe owó ìlú kúmọ-kùmọ se agbátẹrù rẹ̀

 

Aya Ààrẹ sàpèjúwe ìwà jìbìtì orí ẹ̀rọ ayélujára gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó ń kó ìfàsẹ́yìn bá ìtẹ̀síwájú Orílẹ̀-èdè, Ó wá lo ànfààní náà láti fi àrídájú hàn pé ìsèjọba ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu yóò tẹ̀síwájú láti wá ojútùú sí ìsòro ti n koju awọn ọdọ́ láwùjọ.

 

Comments are closed.

button