Gómìnà Ìpínlẹ̀ Borno Yan Ọ̀gbẹ́ni Mustapha Mainu Sí Ipò Alága Ìgbìmọ̀ Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Kílọ̀bù El-Kanemi Warriors
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Borno Yan Ọ̀gbẹ́ni Mustapha Mainu Sí Ipò Alága Ìgbìmọ̀ Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Kílọ̀bù El-Kanemi Warriors
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Borno Babagana Umara Zulum, ti fọwọ́ sí iyansipo Mustapha Ibrahim Mainu sí Ipò Alága Ìgbìmọ̀ Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Kílọ̀bù El-Kanemi Warriors

Wọ́n yán sípò Alága gẹ́gẹ́bí akitiyan rẹ fún ìdàgbàsókè eré bọ́ọ̀lù ni ìpínlẹ̀ náà.
Pẹlú ọgbẹni Mustapha Mainu ni Tahir Bala ni wọn daruko rẹ̀ bi akọwe fún ìgbìmọ̀ náà, àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ tó kù ni:
Waziri Isa, Usman Mohammed Zumami, Ibrahim Mohammed, àti asoju fun komisọ́na àwọn olọ́pàá,Alhaji Maliki Mohammed.
Gómìnà náà kì gbogbo àwọn ti wọn yàn kú oríire wípé ki wọn sa ipa tiwọn láti jẹ́ kí ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù El-Kanemi Warriors FC tẹ síwájú ati fún ìdàgbàsókè gbogbo eré ìdárayá ni ìpínlẹ̀ náà.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san