Ìjọba Ìpínlẹ̀ Kogi Mú Àdíkù Bá Ìgbòkè-gbodò Ọkọ̀ Látàrí Ètò Ìdìbò Ọjọ́ Àbámẹ́ta
Ìjọba Ìpínlẹ̀ Kogi ti se ìfiléde èyí tí kò fi àyègba ìgbòkè-gbodò ọkọ̀ laàrin agogo méje òwúrọ̀ sí agogo mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta
Ọ̀gbẹ́ni Kingsley Fanwo tí ó jẹ́ kọmísọ́nà fún ìfọ̀rọ̀léde ni ó so ọ̀rọ̀ náà ní ọjọ́ Ẹtì, ní ìlú Lọkọja, lójúnà àti se ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tí kò ní ẹja-n-bákàn nínú ní ìpínlẹ̀ Kogi
Kọmísọ́nà pàrọwà sí àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ náà láti jáde lọ́pọ̀ yanturu fun ìkópa nínú ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ láti yan àwọn asojú wọn. Ó wá fi àrídájú léde wípé ìjọba yóò pèsè ààbò tí ó péye fún ìkẹ́sẹjárí ètò ìdìbò náà