Take a fresh look at your lifestyle.

Ayò Ẹlẹ́yin Lórí Tábìlì: Aruna Wà Ní Ipò Kọkàndínlógún Lágbáyé

76

 

Ogbontarigi agbábọ́ọ̀lù ẹlẹ́yin lórí tábìlì ọmọ Nàìjíríà, Quadri Aruna, ti wa ni ipo kọkàndínlógún lagbaye bayii lára àwọn to dara ju ninu àtẹ ìwọ̀n ITTF ti won ṣẹṣẹ gbe jade.

Aruna bẹrẹ ìdíje ITTF agbaye-Macao 2024 dáradára nipa lilu alatako rẹ, Daniel Gonzalez ni àlù yìrá pẹ̀lú ayò mẹ́rin sí òdo 4-0 (11-6, 11-4, 11-6, 11-6).

Aruna ló ń lékè ìsòrí rẹ̀ báyìí .
“Inú mi dùn. Ẹlẹẹkẹta mi leyi ni Macao, o sí jẹ àkọ́kọ́ ti máa kọkọ borí ayo mi ni Macao, inú mi Dun jọjọ” . Aruna ló sọ èyí nígbà tó borí ìdíje rẹ̀ àkọ́kọ́.

Olùborí ìdíje ẹlẹẹkẹtala irú rẹ ilẹ̀ Adulawọ, Omar Assar ti orílẹ̀-èdè Egypt
ló wa ni ipò kẹrìndínlógún lagbaye bayii lára àwọn to dara ju ninu àtẹ ìwọ̀n ITTF ti wọ́n ṣẹṣẹ gbe jáde.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.