Nípa Ìdádúró Ìsúná Owó Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin: Adarí Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Pè Fún Ìtẹ̀síwájú Ìfọ̀rọ̀-Jomitoro-Ọ̀rọ̀
Adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Adebo Ogundoyin ti pè fún ìtẹ̀síwájú ìfọ̀rọ̀-wérọ̀ láàrin ẹgbẹ́ àpapọ̀ àwọn ọmọ asòfin àti àwọn gómìnà láti mú àbádòfin tí ó pè fún àdáyanrí owó ìsúná àwọn ọmọ asòfin wá sí ìmúsẹ
Ogundoyi, ẹni tí ó jẹ́ alága àwọn adarí ilé asòfin ìpínlẹ̀ ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ ọ̀rọ̀ náà ní ìlú Ibadan nígbà tí ẹgbẹ́ àwọn ọmọ asòfin ẹka iwọ̀ oòrùn se àbẹ̀wò sí ọ́ọ́fìsì rẹ̀
Ó tẹ̀síwájú pé àwọn ikọ̀ méjéèjì tí ọ̀rọ̀ kàn ní láti sèpàdé pọ̀ láti rí i dájú pé àbádòfin naa wa si imusẹ lati dena wahala ọjọ iwaju