Àyájọ́ Àwọn Obìnrin: Olurẹmi Tinubu Dáwọ̀ọ́ Ìdùnnú Pẹ̀lú Àwọn Obìnrin Ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Aya Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Arábìnrin Olurẹmi Tinubu dunnú pẹ̀lú àwọn obìnrin jákè-jádò Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí àyájọ́ àwọn obìnrin se ń lọ lọ́wọ́ ní àgbáyé
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, aya ààrẹ dúpẹ́ látàrí ipa ribiribi tí àwọn obìnrin kó fún ìdàgbàsókè Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Ó wá pè fún àmójútó pàtàkì àti ìrànlọ́wọ́ fún àwọn obìnrin kí wọ́n le è tẹ̀síwájú nínú ojúse wọn fún ìdàgbàsókè Orílẹ̀-èdè lápapọ̀.