Ní àyájọ́ àwọn obìnrin àgbáyé ti ọdún 2024, àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ pàrọwà sí àwọn obìnrin láti máa kópa nínú ètò ìsèjọba
Ìpè náà wáyé níbi àpérò kan èyí tí àkọmọ̀nà rẹ̀ jẹ́” Ìkópa Àwọn Obìnrin Nínú Ètò Ìsèjọba Fún Ọjọ́ Iwájú Rere” tí ó wáyé ní ìlú Abuja, Nàìjíríà
Asojú agbátẹrù ètò náà, arábìnrin Mariama Saidou sàlàyé pé, àpérò náà wáyé láti se àwọn obìnrin ní ojúkòkòrò ìkópa tí ó péye nínú ètò ìsèjọba.