Kò dín ní ọlọ́pàá márùn-ún àti àwọn onísòwò nàbì méjì tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn ní òpópónà Hilltop, ìlú Abakaliki, olú ìlú ìpínlẹ̀ Ebonyi
Akọ̀ròyìn ilé Akéde Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fi yéwa pé àwọn olóògbé náà pàdánù ẹ̀mí ní owúrọ̀ kùtù ọjọ́ Ẹtì
Ní àkókò tí kíkọ ìròyìn yìí wáyé, kọmísọ́nà àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, Arábìnrin Augustine Ogbodo wà ní ìpàdé, èyí tí kò fún-un ní ànfààní láti sọ̀rọ̀ lórí ìsẹ̀lẹ̀ náà