Ilé-iṣẹ́ Ọlọ́pàá tí Olú-ìlú Nàìjíríà (FCT) tí mú àwọn ọdaràn mẹ́ta (3) kàn tí wọ́n ń jí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ gbé ní Abuja.
Kọmiṣana ọlọ́pàá tí FCT, C.P Benneth Igweh, sọ pé àwọn afurasi náà jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Ọkùnrin mẹ́rin (4) tó ń jí tàbí já ọkọ̀ gbà lọwọ́ oloún.
C.P Igweh sàlàyé pé àwọn ló ń jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti bí wọ́n ṣé ń gbé ọkọ̀ Hilux bìí mélòó kàn tí wọ́n jí gbé ní Abuja àti àgbègbè rẹ̀, bi tí wọ́n ti kó àwọn ọkọ̀ tí wọ́n jí gbé lọ sí Port-Harcourt láti tà.
Ẹ̀wẹ̀, ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tún bá àwọn ọdaràn méjì mìíràn ní Jabi, Abuja, bí wọ́n ṣé ká ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayédèrú bọndulu ọgọrùn ($100) dọla owó America mọ́ wọ́n lọ́wọ́.

Wọ́n jẹ́wọ́ pé wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Ọkùnrin mẹ́jọ(8) kàn tí wọ́n tá ayédèrú owó dọla náà káàkiri ìpínlẹ̀ lórílẹ̀-èdè yìí èyí tí wọ́n tí tá ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀ fún àwọn olùgbé Abuja kí ọwọ́ palaba wọ́n ó tó segi.