Awakọ̀ ọmọ odún mọkàndínlọ́gbọ̀n (29) ọmọ Ìpínlẹ̀ Gombe, Mallam Suleiman Rabiu tí rìn Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin kilomita (700km) láti Ìpínlẹ̀ Gombe wá sí Abuja láti mọ́ rírí iṣẹ́ Olórí Ààbò Nàìjíríà, Gen. Christopher Gwabin Musa.
Mallam Suleiman, tó kúrò ní ìpínlẹ̀ Gombe ní ọjọ́ kejìlá oṣù kejìlá, ọdún 2024, dé sílùú Abuja ní ọjọ́ kejidinlọ́gbọ̀n oṣù Kejì ọdún 2024, lẹ́yìn tó lo ọjọ́ mẹ́rìndínlógún ní ojú ọ̀nà, láìka ipò ojú ọjọ́ sí.

Ọdọmọkùnrin náà sọ pé; “Ó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò náà láti fi ìmọrírì rẹ̀ hàn fún àwọn iṣẹ́ ríbiríbi àgbàyanu ti CDS tí ṣé.”

Gẹ́gẹ́ bó tí sọ, ààbò àgbègbè àwọn tí gbé pẹẹli sí látari iṣẹ́ àwọn ológun náà.