Ìsàmójútó ìtọ́jú Àwọn Èwe: Aya Gómìnà Ìpínlẹ̀ Anambra Fọwọ́sowọ́pọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Alẹ́nulọ́rọ̀
Aya Gómìnà ìpílẹ̀ Anambra, Arábìnrin Soludo ti fi ọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àjọ aládàníi lójúnà àti wá ojútùú sí ìsòro ìtọ́ju àwọn ọmọdé ní ìpínlẹ̀ Anambra
Arábìrin Soludo pe ìpè náà nígbà tí ó gbàlejò àjọ náà ní ọ́ọ́fìsì Gómìnà tí ó wà ní Amawbia, Ó fi dá àjọ náà lójú pé Òun yóò fi ọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ látàrí isẹ́ rere tí ó ń se
Ó korò ojú sí àwọn ọ̀nà kan tí kò dára, tí à ń lò láti tọ́ àwọn ọmọ ní àwùjọ, èyí tí ó n mu kí ìwà ìbàjẹ́ peléke sí i, ó wá pè fún àmójútó tí ó péye àti ìtọ́sọ́nà èyí tí yóò mú kí ẹ̀yìn ọ̀la àwùjọ wa suwọ̀n