Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Àpapọ̀ Ti Gbáradì Láti Mú Àtúntò Bá Ètò Láti Pín Ohun Amáyédẹrùn Fún Ará Ìlú

110

Mínísítà Fún Ètò Ìnáwó, tí ó tún jẹ́ alákòsóo fún ètò ọrọ̀ ajé, Wale Ẹdun ti sàlàyé pé ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu ti pàṣẹ láti mú àtúntò bá ètò ìgbáyégbádùn ọmọnìyàn láti rí i dájú pé àwọn ọ̀dọ́ tí kò níṣẹ́ lọ́wọ́ rí owó gbà, kí wọ́n sì fún àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún méjìlá ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́ọ́gbọ̀n náírà fún osù mẹ́ta

 

Ó fi ọ̀rọ̀ náà léde lẹ́yìn ìpàdé àpérò ìjọba àpapọ̀ èyí tí ó wáyé ní ọjọ́ Ajé, ní ìlú Abuja, tí ààrẹ Tinubu darí ìpàdé náà

 

Mínísítà tún sísọ lójú ọ̀rọ̀ pé, ìjọba àpapọ̀ tún ń gbé ìgbésẹ̀ míràn láti se ìrànwọ́ fún àwọn ọ̀dọ́ láìpẹ́ jọjọ

 

Comments are closed.

button