Ààrẹ tí sọ pé àbẹwò tí Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu sí Qatar ní èròngbà látí mú ifọkanbalẹ ètò ọrọ̀-àjé láàrín Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àtí ìjọba Qatar lágbára sí.
Olùdámọ̀ràn pàtàkì sí Ààrẹ lórí ìròyìn àtí Ìlànà, Ọ̀gbẹ́ni Bayo Onanuga sọ èyí nínú àlàyé kàn tí wọ́n ṣé fún àwọn Oníròyìn Ilé-iṣẹ́ Ààrẹ lórí ìwé àdéhùn tí ìlú òkèèrè láàrin Ilé-iṣẹ́ ìjọba Qatar àtí Ilé-iṣẹ́ Ìjọba tí Ilẹ̀ Òkèèrè tí Nàìjíríà.
Onanuga Ṣàfihàn ìbáṣepọ̀ tó dàn mọ́ràn láàrín Orílẹ̀-èdè méjèèjì, o wá fí ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àbẹwò Ààrẹ Tinubu jẹ́ tí ìdáhùn sí ìpè tí Emir tí Qatar, Sheik Tamim Bin Hamad Al-Thani.
Olùrànlọ́wọ́ Ààrẹ ṣàlàyé pé Ààrẹ Orilẹ-ede Nàìjíríà náà yóò jíròrò pẹ̀lú olórí Orílẹ̀-èdè Qatar lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì bí ètò ọrọ̀-àjé, ìtẹ̀síwájú ìbáṣepọ̀ láàrín Orílẹ̀-èdè méjèèjì àtí bẹẹbẹẹ lọ́.