Bí owo nǹkan eelo ti wọn nlò ni oko bíi ajile, irúgbìn ati kẹ́míkà míràn ṣe lọ sókè lala ti nkọ awọn agbe lóminú kaakiri orílẹ̀-èdè yìí.
Owo ajile to lo sókè lee jẹ ki ire oko wálẹ̀ bí asiko ojo se n kan ìlẹ̀kùn.
Ni iwon oṣù diẹ sẹyìn, owo nǹkan gbogbo ti lọ sókè ti ko sí rọrùn fún àwọn ènìyàn.
Ọgbin asiko ojo yóò bẹrẹ ni oṣù méjì sí asiko yìí ní àwọn agbègbè kan ni orile-ede yii.
Bayi, awọn àgbẹ ìgbà ọ̀gbẹlẹ̀ ti koro oju sí òwò apo ajile kan to ti fo sí egberun metalelogoji Naira to sì tún lee gbera sọ síwájú síi ni awọn oṣù tó n bọ.
Awon agbe alada- kékeré to n gbin èfó tilẹ̀ ti so ọgbin wọn rọ̀ latari ọ̀dá owó, awó olókun ni ipinle Katsina.
Owó oye ti wọn n ta ajile náà ti lọ sókè ni ipinle Niger. Agbe to n lo omi miran yatọ sí òjò náà ti ni iṣoro ni ipinle Taraba.
Yahaya Mafindito to jẹ́ agbe alada- nla tilẹ sọ pé ” owo ajilẹ̀ ti jẹ ki owo ti wọn fi n da oko lọ sókè “. Bí nnkan gbogbo se n gbowo lori ko tilẹ̀ yé agbẹ̀ mọ́.
Eleyii ti fẹ́ jẹ ki awọn agbe máa dako kékeré tabi lọ máa gbiyanju awọn nǹkan ọ̀gbin miran ti ko nilo ajile taara bí ẹwà, cowpeas abbl.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san