Ilé Luton Town Di Ahoro Lọjọ Isinmi Lẹ́yìn Ìgbà Tí Hojlund Fi Kòbókò Ẹlẹ́nu Méjì Dáwọn Lọ́lá Láàrin Ìsẹ́jú Mẹ́ẹ̀wá.
George Ọláyínká Akíntọ́lá.
Agbabọọlu Man-U to tun jẹ ọmọ orilẹ-ede Danish, Rasmus Hojlund, fi Luton lakalaka laarin isẹju mẹwa, tí ò sí dá mi àwọ̀n lemeji laarin isẹju mẹwa yii, eyi to mu ki Man-U gbegba oroke laarin wọn àti Luton Town, ninu idijẹ premier league ni ọjọ isinmi lori papa iṣere Kenilworth Road ní Luton, Orilẹ-ede England.

Ẹgbẹ Agbabọọlu Manchester United fi Hojlund, Marcus Rashford àti Alejandro Garnacho siwaju lori papa, àwọn mẹtẹta yii, pitu bo ṣe wu wọn
Hojlund mi àwọ̀n laarin isẹju kan ti o fi Man-u si iwaju, ki o tun to fi goolu kan si ni isẹju keje
Ẹgbẹ Agbabọọlu Luton Town naa o sinmi rara, nigba ti o di isẹju kẹrìnlá, Carlton Morris ti Luton Town naa fi ori wé bọọlu sinu àwọ̀n.

Lẹ́yìn tí wọ́n parí eré bọ́ọ̀lù yìí, Man-U sin Luton kúrò lórí pápá pẹ̀lú àmì ayò méjì sí ẹyọkan
George Ọláyínká Akíntọ́lá.