Ẹ gba Àwọn Ọmọ Níyànjú Láti Lọ Sí Ilé Ẹ̀Kọ́ – Ìjọba Ìpínlẹ̀ Kano Gba Àwọn Òbí Nímọ̀ràn
Ìjọba ìpínlẹ̀ Kano, ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Àréwá Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti pàrọwà sí àwọn òbí, ní papàá jùlọ àwọn ìyá, láti rí i dájú pé àwọn ọmọ lọ sí ilé ẹ̀kọ́, èyí tí yóò sé ìgbélárugẹ fún ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ tí ìjọba ìpínlẹ̀ náà sàgbékalẹ̀
Kọmísọ́nà Fún Ètò Ẹ̀kọ́ ní ìpínlẹ̀ náà, Umar Doguwa ni ó pe ìpè náà níbi àpérò kan tí ó wáyé pẹ̀lú àwọn obìrin láti sọ pàtàkì ẹ̀kọ́ àwọn ọmọdébìrin fún ìdàgbàsókè àwùjọ
Ó sàlàyé pàtàkì ẹ̀kọ́, àtipé ìjọba kòní fi àyè gba àìse déédé akẹ́kọ̀ọ́, pípẹ́ dé ilé ìwé àti àwọn ìwà tí kò bójúmu míràn