Igbákejì Adarí Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin, Benjamin Okezie Kalu fi ẹ̀dùn ọkàn hàn látàrí ìpapòdà olùdarí Ilé Ìfowópamọ́ Aceess, Ọ̀gbẹ́ni Herbert Wigwe, ìyàwó àti ọmọkùnrin rẹ̀ nínú ìjàm̀bá ọkọ̀ òfurufú ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní òpin ọ̀sẹ̀
Kalu tún kẹ́dùn lórí ikú Abimbọla Ogunbanjọ, aláṣẹ àti olùdarí ilé isẹ́ (NGX Group) tẹ́lẹ̀rí àti àwọn yókù tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn
Ìkẹ́dùn náà wáyé láti ẹnu olùfọ̀rọ̀léde igbákejì adarí ilé asòfin, Ọ̀gbẹ́ni Levinus Nwabughiogu ni ọjọ Aiku. Kalu sàpèjúwe ikú náà gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó báni lójijì, tí ó sì bani lọ́kàn jẹ́