Ẹ Lọ Ọ Fọkàn Balẹ̀: Shinkafi Pàrọwà Sí Àwọn Alátìlẹyìn Rẹ̀ Látàrí Àbájáde Èsì Àtúndì Ìbò
Ògúnná gbòngbò kan nínú ẹgbẹ́ òsèlú APC, Ọ̀mọ̀wé Sani Shinkafi ti pàrọwà sí àwọn ènìyàn ẹkùn Shinkafi, ìpínlẹ̀ Zamfara láti fọkàn balẹ̀ látàrí àbájáde èsì ìdìbò tí ó wáyé ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ní ìpínlẹ̀ náà
Shinkafi pe ìpè náà nínú ọ̀rọ̀ kan tí agbẹnusọ rẹ̀, Alhaji Yariman Ganuwa sọ fún àwọn oníròyìn ní ọjọ́ ìṣẹ́gun, ní ìlú Abuja
Ó sàlàyé pé ẹgbẹ́ APC tako ìkéde ìjáwé olúborí Mustapha Shinkafi ti ẹgbẹ́ òsèlú PDP, àtipé ẹgbẹ́ APC yóò mórí lé ilé ẹjọ́ níbi tí ìdájọ́ òdodo yóò ti wáyé