Ẹ Fọkàn Balẹ̀, Òpin Yóò Débá Àìrajaja Ètò Ọrọ̀ Ajé Láìpẹ́ Jọjọ- Ìjọba Àpapọ̀ Fi Àrídájú Léde
Ìjọba Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ wípé òpin ti débá Wàhálà àti ìdààmú tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kojú látàrí yíyọ ìrànwọ́ orí epo rọ̀bì
Mínísítà Fún Ìfọ̀rọ̀léde, Mohammed Idris ni ó síṣọ lójú ọ̀rọ̀ fún àwọn oníròyìn ní alẹ́ ọjọ́ ìṣẹ́gun lẹ́yìn ìsúnsíwájú ìpàdé àwọn ìgbìmọ̀ tí ó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìpèsè oúnjẹ èyí tí alákòóso iṣẹ́ ààrẹ, Fẹmi Gbajabiamila ń darí
Ó sàlàyé okùnǹfà ìpàdé náà, èyí tí ó wáyé láti wá ojútùú sí ìfẹ̀hónúhàn ọjọ Ajé, ní ìlú Minna