Ìjọba Ìpínlẹ̀ Abia ti buwọ́lu ìsàgbékalẹ̀ ibùdó ìsàyẹ̀wò ohun èlò ìkọ́lé ní ìlú Umuahia
Ìgbésẹ̀ náà wáyé láti dènà lílo àwọn ohun èlò ayédèrú, lójúnà àti gbógunti ìsẹ̀lẹ̀ ilé dídàwó ní àwùjọ
Alákòóso ètò ìkọ́lé àti ìdàgbàsókè àwùjọ, Ọ̀gbẹ́ni Kingsley Agomoh ni ó fi ọ̀rọ̀ náà léde ní ìlú Umuahia, níbi tí ó ti fi ìgbáradì ìjọba hàn láti se àmójútó àwọn ohun èlò ìkọ́lé láwùjọ.