Ẹlẹ́ṣẹ̀ ayò ọmọ Egypt, Mohamed Salah yóò padanu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Africa Cup of Nations (AFCON) méjì látàrí ìfarapa ẹsẹ to wáyé ni ọjọ Ọjọ́bọ̀ níbi ti ikọ̀ rẹ̀ ti parí pẹlu ayò méjì méjì (2-2) pẹ̀lú Ikọ̀ Ghana ni ìlú Abidjan, àjọ Egyptian Football sọ èyí.
Ni ọjọ Eti, dókítà ilẹ̀ Egypt, Mohamed Abu El-Ela so pé Salah tilẹ fẹ tẹsiwaju nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tó ṣe pàtàkì náà ṣùgbọ́n nígbà ti ìrora náà pọ, ó sọ pe kí wọn yọ òun síta.
Salah sọ bọ́ọ̀lù Golí wòó ki n gba sí ọ(penalty) sínú àwọ̀n ni ọjọ́ Àìkú fún ikọ̀ Egypt láti ta ọ̀miì (2-2) pẹlu ikọ̀ Mozambique. Bakanna ni ọjọ́ Ojọ́rú, ikọ̀ Egypt wa làtẹ̀yìnwá láti tún ta ọ̀mìn pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Ghana. Wọ́n nílò àṣeyọrí nínú ìdíje tó ń bọ pẹ̀lú Ikọ̀ Cape Verde láti tẹẹ síwájú lọ ipele komeseoyọ ẹlẹ́ni mérìndínlógún.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san