Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpínlẹ̀ Kwara: Àwọn Èsọ́ Ọmọ Ogun Civil Defence Sọ Ìmọ̀ Ajọ́mọgbé Di Òtu Bántẹ́

199

 

Àwọn ẹ̀ṣọ́ ọmọ ogun Nigeria Security and Civil Defence Corps NSCDC ni ìpínlẹ̀ Kwara, àárín gbùngbùn Nàìjíríà ti sọ ìmọ afunrasí tó fẹ jí àwọn ọmọ ilẹ ìwé gbé ni ìlú Ìlọrin, Olu ilu Kwara di òtu bántẹ́.

Afurasi, Yusuf Ajaka ọmọ ọdún metadinlogoji ni won gbámú ni agbègbè
Opomalu, ìlú Ilorin nibi ti o ti n gbiyanju láti ji àwọn ọmọ ilé ìwé ti wọn n ti ile ẹ̀kọ́ bọ̀ gbé.

Ọ̀gágun àjọ NSCDC ti ìpínlẹ̀ Kwara, Umar Mohammed fi otitọ gbígbá àwọn afurasi náà múlẹ nigba to n ba àwọn oniroyin sọrọ ní Ìlọrin.

Ọ̀gbẹ́ni Mohammed tun di léde pé, àwọn afunrasí meji miran, Susan Oyewole, ọmọ ogójì Odun , àti Anafi Isiaka, odun metalelogoji, ni won gbamu ni àìpẹ yìí fun esun títè òfegè ọjọ́, àkókò àti ọdún sórí ọja Vita Milk Energy tiwon sí n ta fun àwọn oníbàárà ti ènìyàn kò fura sí.

Nígbà ti wọ́n fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹnu wò, ọgbẹni Anafi jẹ́wọ́ pé òun bẹrẹ òwò burúkú náà pèlú Iyaafin Susan to jẹ onísòwò láti ọdún 2023 tó gba oun láti ṣiṣẹ́ fún òun pẹlú àdéhùn owó gọbọyi.O tún jewo pé àwọn wà nínú owo títẹ òfegè ọjọ́, àkókò àti ọdún sori ọja Vita Milk Energy .

 

Tèmítọ́pẹ́ Óbísẹ̀san

Comments are closed.

button