Take a fresh look at your lifestyle.

Wọ́n Ti Fi Ẹ̀sùn Ìpànìyàn Kan Olórí Ẹgbẹ́ Òkùnkùn Ní Orílẹ̀-èdè Kenya Látàrí Sísekúpa Àwọn Ọmọdé Tí Ó Dín Díẹ̀ Ní Igba

154

Adájọ́ ti pàṣẹ kí olórí ẹgbẹ́ òkùnkùn ní Orílẹ̀-èdè Kenya, Paul Mackenzie àti àwọn ọgbọ̀n míràn lọ se àyẹ̀wò ọpọlọ  síwájú kí wọ́n tó kojú ẹ̀sùn ìpànìyàn  níbi tí wọ́n ti sekúpa àwọn ọmọdé tí ó dín díẹ̀ ní igba, èyí tí wọ́n hú òkú wọn jáde nínú osù kẹrin ọdún tí ó kọjá nínú igbó ńlá Shakahola

 

Ìròyìn fi yéwa pé, Mackenzie tí ó jẹ́ olórí ilé ìjọsìn (Good News Church) ni ó pàṣẹ kí àwọn olùjọsìn fi oúnjẹ sílẹ̀ , kí wọ́n sì má mu títí ẹ̀mí yóò fi bọ́ lọ́rùn wọn, kí wọ́n le è jogún iyè àìnípẹ̀kun.

 

Ó lé ní irinwó òkú ènìyàn tí wọ́n hú jáde nínú igbó, èyí tí ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ tí ó sì pọ̀ jùlọ ní àgbáyé nínú iṣẹ́ láabi àwọn ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn

 

Comments are closed.

button