Take a fresh look at your lifestyle.

Ọ̀gá Àgbà Kan Ní Ẹka Ìjọba Àpapọ̀ Pàrọwà Sí Àwọn Òsìṣẹ́ Láti Mú Iṣẹ́ Ní Okúkúdùn Kí Wọ́n Sì Siṣẹ́ Dé Ògóngó

128

Ọ̀gá Àgbà kan ní ẹka ìjọba àpapọ̀ fún ìsàkóso àwọn òsìṣẹ́, Ọ̀gbẹ́ni Omachi Raymond Omeka ti gba àwọn òsìṣẹ́ níyànjú láti mú iṣẹ́ síṣe ní ọ̀kúkúdùn fún àseyọrí tí ó peregedé

 

Ọ̀gbẹ́ni Omeka pe ìpè náà nígbà tí wọ́n tẹ́wọ́ gbà á ní ẹka ìjọba àpapọ̀ fún àmójútó àwọn òsìṣẹ́, níbi tí ó ti sàdéhùn pé ẹ̀bùn ìrànwọ́ ń bẹ fún àwọn tí ó bá siṣẹ́ dójú àmì, tí ìjẹníyà sì wà fún àwọn onímẹ̀lẹ́ẹ́

 

Gẹ́gẹ́ bí ó se sọ, ìpèsè ohun ìgbáyégbádùn fún àwọn òsìṣẹ́ se pàtàkì tí yóò sì jẹ́ ohun àmójútó. Ó lo ànfààní náà láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu àti alákòóso ẹka ìjọba àpapọ̀ fún àwọn òsìṣẹ́, Ọ̀mọ̀wé Fọlashade Yẹmi-Ẹsan.

 

Comments are closed.

button