Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Ẹjọ́ Gíga Da Ìrawọ́ Ẹ̀bẹ̀ Tí Ẹgbẹ́ Òsèlú ADC Se Láti Tako Ìjáwé Olúborí Gómìnà Mohammed Yahaya Ti Ìpínlẹ̀ Gombe Nù

143

Ilé Ẹjọ́ gíga ti da ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ ti olùdíje sí ipò gómìnà lábẹ́ ẹgbẹ́ òsèlú ADC, Nafiu Bala se láti tako ìjáwé olúborí gómìnà Muhammad yahaya ti ìpínlẹ̀ Gombe

 

Àwọn adájọ márùn-ún tí Adájọ́ Kudirat Kekere-Ẹkun darí ni ó da ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ náà nù ní kété tí olùpẹ̀jọ́ ju ọwọ́ sílẹ̀ lórí ìpẹ̀jọ́ rẹ̀

 

Lórí ìgbẹ́jọ́ kàn náà, ilé ẹjọ́ sún ìdájọ́ síwájú sí ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kọkàndínlógún, osù kíní ọdún 2023 lórí ìdájọ́ fún ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ tí Jibrin Barde se, ẹni tí ó jẹ́ olùdíje lábẹ́ ẹgbẹ́ òsèlú PDP.

 

 

Comments are closed.

button