Orile-ede China ti pe fún imugbooro ipe ìpàdé àlàáfíà latari ogun ní ìlú Gaza.
Nigba ti o n sọ̀rọ̀ ní orile-ede Egypt, Mínísítà ọrọ ile òkèèrè tí orile-ede China ti pe ètò láti jẹ ki àlàáfíà jọba ni kíámọ́sá láàrin orílẹ-èdè Israel àti Palestine.
Eleto ìlera ile Gaza ti sọ pé Merinlelogun ẹgbẹ̀run eniyan ni wọn gbemi mi latayri Ikọlù Israẹli ti Ọgọ́ta ẹgbẹ̀run sí ti farapa.
Aare, Benjamin Netanyahu ti sọ pé kò sí ọrọ̀ nínú ìdáwọ́dúró ogun àfi ìgbà ti àwọn bá ri ẹ̀yìn àwọn ọlọtẹ̀ Hamas, ti wọn sì gba gbogbo àwọn ti wọ́n ti kó ni ìgbèkùn padà.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san