Take a fresh look at your lifestyle.

Ohun Ìwúrí Ní Ìjáwé Olúborí Lawal Jẹ́ Fún Ìpínlẹ̀ Zamfara- Kọmísọ́nà

139

Komísọ́nà Fún Ìfọ̀rọ̀léde Àti Àṣà ní Ìpínlẹ Zamfara, Alhaji Mannir Haidara ti sàpèjúwe ìdájọ ilé ẹjọ́ àpapọ̀ lórí ìdíje sí ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Zamfara gẹ́gẹ́ bí èyí tí yóò mú ìdàgbàsókè bá ìjọba tiwa-n-tiwa àti ìpínlẹ̀ Zamfara

 

Níbi ìdájọ́ ilé ẹjọ́ àpapọ̀ tí ó wáyé ní ọjọ́ Ẹtì, ó fi ìdi ìjáwé olúborí Dauda Lawal múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí gómìnà ti wọn dìbòyàn fún ìpínlẹ̀ Zamfara

 

Haidara sàpèjúwe ìdájọ́ náà gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó dára fún ìpínlẹ̀ Zamfara, Ó wá rọ àwọn olólùfé ẹgbẹ́ PDP ní ìpínlẹ̀ Zamfara láti jìnà sí àwọn ìwà tí ó le è da ọmi àlàáfíà ìlú rú, kí wọ́n sì se àjọyọ̀ ní ìwọ̀tún-wọ̀nsì.

 

Comments are closed.

button