Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Ejọ́ Gíga Jùlọ Da Ẹjọ́ Tí Ẹgbẹ́ Òṣèlú SDP Pè Nù

183

 

Ilé Ejọ́ gíga jùlọ ni orilẹ-ede yii ti da ẹjo kòtẹ́milọ́rùn ti Ẹgbẹ́ Oselu SDP àti Oludije gomina re, Dókítà Umar Ardo pé lati takò ìjàwé olubori Ahmadu Fintiri gege bi gomina ipinle Adamawa nu.

Ìwé ìpèjọ́, SC/CV/1219/2023 náà ni Ilé Ejo Giga jùlọ ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà dànù bíi omi ìsanwọ́ latari pe ko kun oju òṣùwọ̀n.

Ẹgbẹ́ Òṣèlú SDP àti Oludije rẹ̀ ní ìbò ẹgbẹ̀rún mẹfa lati takò Fintiri Ti Egbe oselu Peoples Democratic Party, PDP, to ní ibo ogbon lé ní irinwo ẹgbẹ̀run ninu ibo ọjọ kejidinlogun, oṣù kẹta, odun 2023.

Adájọ́ John Inyang Okoro, to síwájú ìgbìmọ̀ eleni marun adajo da ejo naa ni.
Ilé ẹ̀jo giga julọ ni orilẹ-ede yìí wa fi idi okodoro ibo to kun oju oṣuwọn ló gbé gomina Adamawa wole sọọ hàn bi ẹni tí àwọn ènìyàn dibo yàn.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button