Take a fresh look at your lifestyle.

Arábìnrin Asantewaa Ṣètò Látí Fí Ìtàn Balẹ̀ Nínú Ìwé ‘Guinness World Record’

311

Arábìnrin ọmọ Orílẹ̀-èdè Ghana kàn, Afua Asantewaa Aduonum tí wà lórí ìrìn-àjò láti fi orúkọ rẹ̀ sínú ìwé Àgbáyé ‘Guinness World Record’ fún ìdíje eré orin tó pẹ́ jùlọ.

Nínú ìgbìyànjú rẹ̀ látí fí orúkọ rẹ̀ parọ tí Sunil Waghmare ọmọ India tó kọrin fún ọgọ́rùn àtí márún (105hrs) wákàtí nínú ìwé ìtàn Àgbáyé ‘Guinness World Record’ ní Oṣù Kẹ́ta, ọdún 2012, Afua tí n kọ́ àwọn orin Ghana leralera ní abúlé Akwaaba.

Ìrìn-àjò Afua tó bẹ̀rẹ̀ ní ògànjọ́ òru ní ọjọ́ Kẹ́rinlélogun (24th) Oṣù Kejìlá pẹ̀lú ìrètí látí parí ní ọjọ́ kẹtadinlọgbọn (27th) Oṣù Kejìlá, èyítí o tumọ sí pé yóò kọrin láìsí ìdúró fún ọjọ́ mẹ́rin wákàtí mẹ́sàn.

Ìgbákejì Ààrẹ orílẹ̀-èdè Ghana Mahamudu Bawumia tún wà níbẹ̀ látí ṣé àtìlẹ́yìn rẹ̀.

Comments are closed.

button