Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti kẹ́dùn ikú Arakunrin Rotimi Akeredolu to jẹ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ondo títí di ọjọ́ ikú rẹ̀ lẹ́ni ọdún Mẹ́tàdínláàdọ́rin (67).
Makinde, ẹni tó fi olóògbé Akeredolu we ẹni tó já fitafuta fún iṣọkan Ẹkùn Iwọ oòrùn Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà náà ló ti sọ awọn ohun ribiribi ti Akeredolu gbé ike ayé ṣe.
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ jẹ kó di mímọ̀ pé Akeredolu ati òun lo ṣe okùnfà ìfilọ́lẹ̀ ikọ Amọtẹkun to fi jẹ́ kí ètò ààbò rẹsẹ̀ walẹ̀ ni Ẹkùn náà.
Bákan náà ni Makinde tẹnu mọ pé ìdúróṣinṣin lórí ọ̀rọ̀ tó ní ṣe pẹ̀lú ìsọ̀kan àti ìlọsíwájú ẹkùn iwọ oòrùn yẹ kó jẹ́ ẹkọ fún gbogbo adarí.
Makinde wa tun ba aya, ọmọ àti Ìjọba pẹ̀lú àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ Ondo kẹ́dùn ìpapòdà ẹni tó jẹ́ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ondo títí di ọjọ’Ru, ọjọ ketadínlọgbọn oṣù Kejìlá ọdún 2023.
Abiola Olowe
Ìbàdàn