Ìyàwó Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Oluremi Tinubu, tí mọ́ rírí àwọn ìrànlọ́wọ́ tí àwọn àgbàlagbà ṣé sí àwọn ìdàgbàsókè Orílẹ̀-èdè yìí, èyí tó fá àgbékalẹ̀ ‘Renewed Hope Initiative, Elderly Support Scheme, (RHIESS).’
Ó rọ àwọn àgbàlagbà orílẹ̀-èdè náà pé kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn olólùfẹ́ wọ́n lágbára sí i kí wọ́n lè gbádùn ìgbésí ayé ọlọ́rọ̀ tí wọ́n ní ìrètí sí.
Ìyááfín náà sọ̀rọ̀ yí níbí ìbẹrẹ ti RHIESS ní Abuja, Olú ìlú Orílẹ̀-èdè náà.
![]()
O ṣé àkíyèsí pé àkókó ọdún kérésìmesì yí jẹ́ àkókò ayò àtí ìtùnú àtí pé kò sí ọmọ Orílẹ̀-èdè yìí kọ̀ọ̀kan laibikita sí ọjọ́-orí tàbí ẹ̀yà tí á gbọ́dọ̀ fí sílẹ̀.
Bákan náà ní ọgá àgbà àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò, General Christopher Musa, dúpẹ púpọ̀ lọ́wọ́ Àyá Ààrẹ náà fún ìpèsè àtí àtìlẹ́yìn rẹ̀ ní ìgbàgbogbo fún àwọn ọmọ Ológun àtí àwọn ọlọ́pàá.
Làkókò ètò náà tó wáyé káàkiri àwọn gbogbo àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rindínlogoji (36) àtí Olú-ìlú (FCT), ṣé àfihàn àwọn ẹbùn owó tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọrùn kàn Náírà fún àwọn àgbàlagbà àádọtalélúgbá (250) ní ìpínlè kàn, FCT àti àwọn àgbàlagbà Ológun.
Àpapọ̀ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé àádọ́ta mílíọ̀nù Náírà ni wọ́n pín sí. Àpò ìrẹ́sì àti àwọn oúnjẹ mìíràn àtí àyẹwò àrà ní a tún fún àwọn tó kópa.